Postproverbials

Postproverbial: A kìí gba àkàkà lọ́wọ́ akítì, kò sẹni tó máa gba nǹkan tó jẹ́ t’èmi lọ́wọ́ mi.
Translation: No one stops a monkey from somersaulting; no one can claim what belongs to me.
Proverb: A kìí gba àkàkà lọ́wọ́ akítì, a kìí gba’lée baba ẹni lọ́wọ́ ẹni.
Translation: No one stops a monkey from somersaulting; no one can claim a child’s father’s house from him.
Language - Region: Yoruba (Nigeria)
Read more
Postproverbial: A kì í f’ọmọ ọrẹ̀ b’ọrẹ̀, ọmọ tó bá gbọ́n!
Translation: No one sacrifices the child of an idol to the same idol, that’s only when the child is smart.
Proverb: A kì í f’ọmọ ọrẹ̀ b’ọrẹ̀.
Translation: No one sacrifices the child of an idol to the same idol.
Language - Region: Yoruba (Nigeria)
Read more
Postproverbial: Béèyàn bá f’árí apákan d’ápákan sí, ó d’aláwo nùn-un.
Translation: Should anyone shave one part of the head and leave a portion uncut, he becomes an herbalist.
Proverb: A kì í f’árí apákan ká d’ápá kan sí.
Translation: It is taboo to shave one part of the head and leave a portion uncut.
Language - Region: Yoruba (Nigeria)
Read more
Postproverbial: Àjọjẹ kò dùn, f’ẹ́ni tó l’áhun.
Translation: Sharing the meal cannot be enjoyable, for the miserly one.
Proverb: Àjọjẹ kò dùn, b’ẹ́nì kan kò ní.
Translation: Sharing the meal cannot be enjoyable, when one in the group has not.
Language - Region: Yoruba (Nigeria)
Read more
Postproverbial: À jẹ ìwèyìn, ló ba ẹlẹ́dẹ̀ jẹ́; kí lódé tí elede ko fí w’ẹ̀yìn?
Translation: Selfishness – eating without hindsight is the flaw of the pig; why would the pig not look back?
Proverb: À jẹ ìwèyìn, ló ba ẹlẹ́dẹ̀ jẹ́.
Translation: Selfishness – eating without hindsight is the flaw of the pig.
Language - Region: Yoruba (Nigeria)
Read more
Postproverbial: Àìtètè m’ólè, olè ń sálọ.
Translation: In the hesitation to catch the thief, the thief scampers away.
Proverb: Àìtètè m’ólè, olè ń m’ólóko.
Translation: In the hesitation to catch the thief, the thief arrests the farmer.
Language - Region: Yoruba (Nigeria)
Read more
Postproverbial: Àìtètè m’ólè, olè gbón sí i.
Translation: In the hesitation to catch the thief, the thief proves wiser.
Proverb: Àìtètè m’ólè, olè ń m’ólóko.
Translation: In the hesitation to catch the thief, the thief arrests the farmer.
Language - Region: Yoruba (Nigeria)
Read more
Postproverbial: Àìtètè l’óbìnrin bí ọ̀lẹ làá rí.
Translation: A prolonged bachelorhood does not prevent child-bearing, it only makes one look like a slacker.
Proverb: Àìtètè l’óbìnrin kò pé ká má bí ọmọ, àrẹ̀mọ wọn níí kéré.
Translation: A prolonged bachelorhood does not prevent child-bearing, only the first born will come too late and young.
Language - Region: Yoruba (Nigeria)
Read more
Postproverbial: Àìsí nílé ológbò, èkúté n sá káàkiri.
Translation: The cat is not in the house, the mouse runs (fools) around.
Proverb: Àìsí nílé ológbò, ilé d’ilé èkúté.
Translation: The cat is not in the house, the home becomes the playground of rats.
Language - Region: Yoruba (Nigeria)
Read more
Postproverbial: Àìsí nílé ológbò, tí n mu‘mè háyà’ fi n di ‘mègídá’.
Translation: The cat is not in the house, (and) the tenant suddenly becomes the landlord.
Proverb: Àìsí nílé ológbò, ilé d’ilé èkúté.
Translation: The cat is not in the house, the home becomes the playground of rats.
Language - Region: Yoruba (Nigeria)
Read more