Proverbs in yoruba-nigeria

Curator(s)

Prof. Aderemi Raji-Oyelade

remraj1@gmail.com

University of Ibadan, Ibadan, Nigeria.

Proverb: Kò sí ẹni tí kìí rẹ̀.
Translation: There is no one who is never exhausted.
Language - Region: yoruba-nigeria
Proverb: K’ójú má ríbi, ẹsẹ̀ loògùn un rẹ̀.
Translation: That the eyes may not witness calamity, the leg is its solution.
Language - Region: yoruba-nigeria
Proverb: Ìyàwó ọlẹ là á gbà, kò sẹ́ni tó lè gba ọmọ ọlẹ.
Translation: It is only the wife of the lazy man that can be taken, no one can claim the child of the lazy man.
Language - Region: yoruba-nigeria
Proverb: Ìwà l’ẹwà lọ́dọ̀ t’èmi.
Translation: Character is beauty to me.
Language - Region: yoruba-nigeria
Proverb: Ìrà á pé, ìranù ni kò suwọ̀n.
Translation: Vanity may pay, vagabondage is not proper
Language - Region: yoruba-nigeria
Proverb: Ilé Ọba tó jó, ẹwà ló bù kún un.
Translation: The palace that is burnt will make a more magnificent edifice.
Language - Region: yoruba-nigeria
Proverb: Igi gogoro má gún mi lójú, àtòkèrè latí n wòó.
Translation: So that we may not be blinded by the tall, pointed tree, one must watch it from afar.
Language - Region: yoruba-nigeria
Proverb: Ibi pẹlẹbẹ ni a ti ń mú ọ̀ọ̀lẹ̀ jẹ.
Translation: It is from the base that one eats a beans pudding.
Language - Region: yoruba-nigeria
Proverb: Ìbàjẹ́ ọjọ́ kan, kì í tán l’ógún ọdún.
Translation: A day of defamation and dishonour never ends in twenty years.
Language - Region: yoruba-nigeria
Proverb: Gàǹbàrí pa Fúlàní, kò lẹ́jọ́ nínú.
Translation: If the Hausa man kills the Fulani, it is not actionable.
Language - Region: yoruba-nigeria