Proverbs in yoruba-nigeria

Curator(s)

Prof. Aderemi Raji-Oyelade

remraj1@gmail.com

University of Ibadan, Ibadan, Nigeria.

Proverb: Àgbò tó tà’dí m’ẹ́yìn, agbára ló lọ mú wá.
Translation: The ram that charges backward, readies itself for another onslaught.
Language - Region: yoruba-nigeria
Proverb: Olè tó gbé kàkàkí Ọba, níbo ni yó ti fọ́n?
Translation: The thief that stole the king’s trumpet, where would he blow it?
Language - Region: yoruba-nigeria
Proverb: Èké d’áyé, áásà d’àpòmu.
Translation: Deceit becomes the world, dry tobacco becomes the drinker’s concoction.
Language - Region: yoruba-nigeria
Proverb: Ọmọ tó ní ìyá òun kò ní sùn, òun náà kò ní fi ojú kan oorun.
Translation: A child who will not allow his mother to rest will himself stay awake.
Language - Region: yoruba-nigeria
Proverb: Òkèlè àkọ́bù, kìí r’áùn ọbẹ̀.
Translation: The first bolus of a meal, does not lack the full recompense of stew.
Language - Region: yoruba-nigeria
Proverb: Tí a bá fi ọwọ́ ọ̀tún b’ọ́mọ wí, a fi t’òsì fà á mọ́ra
Translation: When we admonish the child with the right hand, we must embrace him with the left.
Language - Region: yoruba-nigeria
Proverb: Sàn-án là á rìn, ajé ní í mú ni pẹkọrọ.
Translation: Life’s journey requires forthrightness; it is the race for riches that causes crookedness.
Language - Region: yoruba-nigeria
Proverb: Òwú ìyá gbọ̀n, lọmọ ó ran an.
Translation: The wool that mother makes out of the cotton, is what her child will sew.
Language - Region: yoruba-nigeria
Proverb: Ọwọ́ ọmọdé kò tó pẹpẹ, t’àgbàlagbà kò wọ akèrègbè.
Translation: The hand of the child does not reach the rafter, that of the elder does not enter the gourd.
Language - Region: yoruba-nigeria
Proverb: Owó ni kẹ̀kẹ́ ìyìn rere.
Translation: Money is the wheel of the good gospel.
Language - Region: yoruba-nigeria