Postproverbials

Postproverbial: Màlúù tí kò ní’rù, ó wà ní Òjé.
Translation: The cow that has no tail is available in Oje.
Proverb: Màlúù tí kò ní’rù, Olúwa níí bá a léṣinṣin.
Translation: As for the cow that has no tail, God is its repellant against flies.
Language - Region: Yoruba (Nigeria)
Read more
Postproverbial: Màlúù tí kò ní’rù, ó wà ní Òyìngbò.
Translation: The cow that has no tail is available in Oyingbo.
Proverb: Màlúù tí kò ní’rù, Olúwa níí bá a léṣinṣin.
Translation: As for the cow that has no tail, God is its repellant against flies.
Language - Region: Yoruba (Nigeria)
Read more
Postproverbial: Kò sí ẹni tí kìí rẹ̀, ó rẹ mọ́sálásí, ó di ilé epo.
Translation: There is no one who is never exhausted, the mosque tires, it becomes a gas station.
Proverb: Kò sí ẹni tí kìí rẹ̀.
Translation: There is no one who is never exhausted.
Language - Region: Yoruba (Nigeria)
Read more
Postproverbial: Kò sí ẹni tí kìí rẹ̀, ó rẹ mọ́sálásí, ó di ilé epo. Ó rẹ wọ́dà, ó kó owó ìjọba jẹ.
Translation: There is no one who is never exhausted, the mosque tires, it becomes a gas station; the warder tires, he embezzles the state fund.
Proverb: Kò sí ẹni tí kìí rẹ̀.
Translation: There is no one who is never exhausted.
Language - Region: Yoruba (Nigeria)
Read more
Postproverbial: Kò sí ẹni tí kìí rẹ̀, àyàfi Ọlọ́run.
Translation: There is no one who is never exhausted, except God.
Proverb: Kò sí ẹni tí kìí rẹ̀.
Translation: There is no one who is never exhausted.
Language - Region: Yoruba (Nigeria)
Read more
Postproverbial: K’ójú má ríbi, gbogbo ara loògùn rẹ̀.
Translation: That the eyes may not witness calamity, the whole body is its solution.
Proverb: K’ójú má ríbi, ẹsẹ̀ loògùn un rẹ̀.
Translation: That the eyes may not witness calamity, the leg is its solution.
Language - Region: Yoruba (Nigeria)
Read more
Postproverbial: Ìyàwó ọlẹ là á gbà, a kìí gba ìyàwó alágbára.
Translation: It is only the wife of the lazy man that can be taken, no one can claim the wife of a powerful man.
Proverb: Ìyàwó ọlẹ là á gbà, kò sẹ́ni tó lè gba ọmọ ọlẹ.
Translation: It is only the wife of the lazy man that can be taken, no one can claim the child of the lazy man.
Language - Region: Yoruba (Nigeria)
Read more
Postproverbial: Ìyàwó ọlẹ là á gbà, tó bá wuni.
Translation: It is (only) the wife of the lazy man that can be taken, if one fancies her.
Proverb: Ìyàwó ọlẹ là á gbà, kò sẹ́ni tó lè gba ọmọ ọlẹ.
Translation: It is only the wife of the lazy man that can be taken, no one can claim the child of the lazy man.
Language - Region: Yoruba (Nigeria)
Read more
Postproverbial: Ẹwà n’ìwà lọ́dọ̀ t’èmi.
Translation: Beauty is character to me.
Proverb: Ìwà l’ẹwà lọ́dọ̀ t’èmi.
Translation: Character is beauty to me.
Language - Region: Yoruba (Nigeria)
Read more
Postproverbial: Irà á pé, ìranù ni kò suwọ̀n; tí í mú arúgbó wọ lẹ̀ggínsì.
Translation: Vanity may pay, vagabondage is not proper; such that makes an old woman wear leggings.
Proverb: Ìrà á pé, ìranù ni kò suwọ̀n.
Translation: Vanity may pay, vagabondage is not proper
Language - Region: Yoruba (Nigeria)
Read more