Proverb: Báòkú, ìṣe ò tán.
Translation: When there’s life, activity does not cease.
Proverb: Àtẹ́lẹwọ́ ẹni kìí tan ni jẹ.
Translation: One’s palm does not betray the bearer.
Proverb: A kìí gbé’lé ẹni ká f'ọrùn rọ́.
Translation: One cannot stay at home and get injured.
Proverb: Tí ará ilé ẹni bá ń’jẹ kòkòrò burúkú, tí kò bá r’ẹ́ni sọ fun un, hùrùhẹrẹ rẹ̀ kò ní jẹ́ kí ará ilé gbádùn.
Translation: When one’s relation feeds on a forbidden insect without being warned, his restive reaction will not allow the neighbours to rest.
Proverb: F’ọ̀tún w’òsì, f’òsì w’ọ̀tún, lọwọ́ fi ńmọ́.
Translation: Washing the left with the right, washing the right with the left, makes the hand clean.
Proverb: Àgbájọ ọwọ́ la fi ń’sọ àyà.
Translation: [With] All hands together we beat the chest in solidarity.
Proverb: Ẹni éégún ńlé, kó máa r’ọ́jú; bó ti ń’rẹ ará ayé náà ló ń’rẹ ará ọ̀run.
Translation: He who is pursued by the masquerade should endure; as the human tires so does the spirit tire.
Proverb: Nala kungheko iquhude liyasa.
Translation: Even when the rooster is not present, the day breaks.
Proverb: Uwar kishiya, kwadon kulle mai yawon banza.
Translation: The mother (matriarch) of co-wives is a padlock for the restless wanderer.
Proverb: Òkùnkùn kò m’ẹni ọ̀wọ̀.
Translation: Darkness does not recognize the noble person.
Proverb: Girman kai rawanin tsiya.
Translation: Pride is the turban of trouble.
Proverb: “Mai zan yi da abinda ya gagare wuta,” inji kishiyar konania.
Translation: “I have no business with a fire fighter,” says the co-wife of a burnt woman.
Proverb: Ong ole kojuwa hwume gen gen ka gba chu gbei.
Translation: Whatever is making the bush to shake must come to the road by and by.
Proverb: Oun tó wà l’ẹ́yìn Ọ̀fà, ó ju Òjé lọ.
Translation: What is after the border of ̀Ọfà is more than the encampment of Òjé.
Proverb: Ó jọ gáte, kò jọ gàté, ó fi ẹsẹ̀ méjì lé lẹ̀ gáte-gàte!
Translation: So steadily, so unsteadily, the matter plants its feet wobbly in the land!
Proverb: Igi gogoro má gùn míi lójú, àtòkèrè la tí ǹ'wó.
Translation: That we may not be blinded by the tall, pointed tree, one must watch it from afar.
Proverb: Òde kìí yá aláṣọ rè.
Translation: Partying never tires the dresser.
Proverb: Ìsúnmọ́ni, là á mọ̀ ṣe ẹni.
Translation: Close association brings understanding.
Proverb: Ara kìí sá f’ára, bíí ti kúrúnà kọ́.
Translation: Bodies do not run from bodies, not with scabies infection.
Proverb: Ká rìn ká pọ̀, yíyẹ níí yẹni.
Translation: Moving in unison brings honour and respect.
Proverb: Ukwu n’aga wam wam wam marakwa na anya n’aga wam wam wam na eleya.
Translation: The leg that walks about should know that the eye that looks around is watching it.
Proverb: Akpa sangha isang isi diagha se mbon ufok edia.
Translation: The one who walks about does not eat what those at home consume.
Proverb: Ibi orí dá’ni sí làá gbé.
Translation: A man’s home is where he should reside.